Ṣebi ẹ gbọ radarada to n tẹnu wọn jade

Spread the love

Ẹgbẹ awọn Fulani onimaaluu ti wọn n pe ni Miyetti Allah sọ lọsẹ to kọja pe aya awọn n ja gan-an? Njẹ ki lo n ja wọn laya, wọn ni bi Atiku ba fi le wọle ibo aarẹ to n bọ yii, yoo pin Naijiria patapata ni, orilẹ-ede naa yoo si fọ labẹ ijọba rẹ. Wọn ni nitori ẹ lawọn ko ṣe ni i dibo fun un, awọn ko si fẹ ki ọmọ Naijiria dibo fun un, ko ma jẹ oun ni yoo pada fọ Naijiria si wẹwẹ. Ko si ohun ti eeyan ko ni i maa ri nilẹ yii ati ni awọn adugbo ti a n gbe yii, oriṣiiriṣii ọrọ rirun ati ọrọ ailọpọlọ ni yoo maa ti ẹnu awọn eeyan jade. Loju awọn yii, wọn n tan wa jẹ niyẹn o, tabi ta ni ko mọ pe ohun to n ja awọn Fulani onimaaluu yii laya ni pe bi Atiku ba wọle, awọn ko ni i ri iru anfaani ipaayan ati ifipa gba ohun olohun ti awọn ni laye Buhari yii, nitori olori Naijiria to ba fẹran Naijiria loootọ, to fẹran awọn eeyan ibẹ, to si fẹran iṣọkan wa, ko ni i maa ṣe ohun ti Buhari n ṣe fun wa yii fun wa. Tabi bawo ni olori wa yoo ṣe laju silẹ ti awọn Fulani yoo si maa pa wa lorukọ pe wọn n da maaluu, ti wọn yoo maa gbe ibọn kiri, ti wọn yoo maa gba oko oloko ati ile onile, ati obinrn olobinrin, ti ko si ni i sẹni kan to le mu wọn. Ta lo mọ pe ẹgbẹ onimaaluu kan wa nilẹ yii to n jẹ Miyetti Allah, ṣebi laye Buhari yii naa la gbọ orukọ ẹgbẹ wọn, to si jẹ awọn ni wọn n paṣẹ bayii, ti wọn n sọ pe ko sẹni to le le awọn nibi kan, nitori gbogbo ilẹ Naijiria tawọn ni. Bo ba jẹ Atiku ni yoo gba wa lọwọ awọn Fulani apaayan yii, Ọlọrun yoo ma jẹ ko wọle o, ko wọle, ki adanu ba awọn afẹmiṣofo, awọn igaara ọlọṣa, adigunjale ti wọn n pe ara wọn ni onimaaluu kiri. Awọn ọmọ Naijiria mọ awọn darandaran tootọ, wọn mọ awọn onimaaluu to jẹ ojulowo ọmọ Naijiria, ti wọn n fi maaluu ṣe iṣẹ aje wọn. Bẹẹ naa ni wọn mọ awọn apaayan ti wọn n fi ibọn da maaluu tiwọn. Awọn onimaaluu gidi ko ni i bẹru, nitori ko sohun ti yoo ṣe wọn. Ṣugbọn awọn adigunjale yii gbọdọ bẹru, nitori laipẹ lai jinna, ina Ọlọrun yoo jo wọn, awọn naa yoo si jere gbogbo aburu ti wọn ṣe.

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.