Ṣebi ẹ gbọ ọrọ owo ti wọn ni ọlọpaa iyawo Buhari ji ko

Spread the love

Boya ẹyin ko ti i gbọ pe wọn mu olori awọn ẹṣọ to n ṣọ iyawo olori orilẹ-ede wa, Aishat Buhari. Orukọ ọkunrin supiritẹndẹnti ọlọpaa naa ni Sani Baba Inna. Wọn ni funra iyawo aarẹ lo ni ki wọn gba ọkunrin naa mu, nitori o ji owo oun kan ko, owo naa si n lọ si bii biliọnu meji ataabọ owo Naira (N2.5b). Wọn ni Aishat ni awọn eeyan kan ti wọn n ṣe itọrẹ-aanu si ileeṣẹ alaanu ti oun da silẹ ni wọn n ko owo naa fun Baba Inna, ṣugbọn ko ko owo naa jiṣẹ, o kan n la a ni, iyẹn niyawo Aarẹ ṣe ni ki wọn ba oun mu un, ki wọn si ri i pe o da owo naa pada, ko pọ ọ jade kia. Ṣugbọn nigba ti awọn ọlọpaa mu Baba Inna, ti wọn wadii lẹnu rẹ titi, o loun ko kowo kan jẹ o, nigba ti wọn si yẹ akaunti rẹ wo, wọn ko ba owo kan nibẹ to to owo gidi, wọn saaji ile ẹ naa, ẹgbẹrun kan Naira pere ni wọn ba. Wọn sọrọ naa fun iyawo Buhari lo ba binu, o ni awọn ọlọpaa n gbe lẹyin ẹ ni nitori ara wọn ni, lo ba ni ki awọn SSS ba oun mu un jare. Akọkọ ni pe lara iwa ibaje to wa lorilẹ-ede yii niyẹn, awọn ọmọ Naijiria ko dibo fun iyawo Buhari, nitori bẹẹ, ko lẹtọọ lati ni ẹṣọ rẹpẹtẹ bẹẹ titi ti yoo fi tun ni olori awọn ẹṣọ, iyẹn ADC, ti yoo maa ṣọ ọ kiri. Bi ọkọ rẹ ba fẹ ki wọn maa ṣọ ọ, iyẹn ni yoo fun un ni ọlọpaa kan tabi meji, ko ju bẹẹ lọ. Bẹẹ ni ko lẹtọọ kankan labẹ ofin ilẹ yii lati maa gba owo kankan lọwọ awọn ọmọ Naijiria tabi awọn ileeṣẹ fun ohunkohun, nitori iwa ilọnilọwọgba ni yoo pada ja si. Ṣugbọn ki i ṣe pe iyawo Buhari ni ọlọpaa to n ṣọ ọ nikan kọ, o ni ileeṣẹ tirẹ, to si jẹ ijọba Naijiria lo n sanwo oṣiṣẹ ati owo awọn ohun gbogbo ti wọn n lo nibẹ, obinrin yii tun ni awọn ọlọpaa tirẹ, wọn si ti sọ ileeṣẹ tirẹ naa di odidi ileeṣẹ ijọba nla. Iru eleyii ko daa, ko bojumu, ibi ti iwa ibajẹ si pin si ni. Ko waa yẹ ko jẹ iru Buhari ti gbogbo wa gbọkan le pe iwa ibajẹ ko ni i si lasiko tirẹ ni yoo faaye gba iru eleyii, titi debii pe wọn yoo tun maa gba owo lọwọ awọn eeyan. Iyawo Buhari ko binu pe ọkunrin ọlọpaa yii gba owo, ohun to n bi i ninu ni pe ko ko owo to gba jiṣẹ, o si fẹ ki wọn ba oun gba owo oun. Awọn wo lo fun un ni owo to to bẹẹ, nibo lo si ti ri wọn. Iṣẹ wo lo ṣe fun wọn, tabi ọja wo ni wọn ra lọwọ ẹ ki wọn too fun un ni iru owo to to bẹẹ yẹn. Nitori kin ni? Ki lo sọ fun wọn, ki lawọn naa si fẹ ko ṣe fun wọn ti wọn fi n fun un lowo. Dajudaju, ki i ṣe nitori ohun meji ni wọn ṣe n fun un lowo yii, nitori ko le gba nnkan fun wọn lọwọ Aarẹ Buhari ni. Iwa ibajẹ gbaa leleyii, ki Buhari tete kilọ fun iyawo rẹ, nitori ọjọ kan n bọ ti gbogbo kinni wọnyi yoo lẹyin, lọjọ ti yoo han saye pe onibajẹ kan ni iyawo aarẹ, ti wọn yoo si fi kinni naa ra Buhari funra rẹ lara. O ṣi n daa bayii o, ki Buhari tete ba iyawo rẹ sọrọ ki aṣiri too tu patapata o.

(18)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.