Ṣe Tunde Bakare ba Buhari sọ ootọ ọrọ ṣa

Spread the love

Ni ọsẹ to kọja yii, olori ijọ Latter Rain, Pastor Tunde Bakare, lọ si Aso Rock lati ri Aarẹ Muhammadu Buhari. Ọrọ naa tilẹ di akọlukọgba, nitori bi oun ti n lọọ ri Buhari bẹẹ ni Minisita eto inawo ilẹ wa, Kẹmi Adeọṣun, naa n lọọ ri ọga rẹ yii. N lawọn eeyan ba ro pe wahala to ba Adeọṣun nitori ọrọ sabukeeti awọn agunbanirọ ti wọn ni ayederu ẹ lo n gbe kiri ni Bakare tori ẹ waa ba Aarẹ lati ba obinrin naa bẹbẹ. Ṣugbọn pasitọ naa tete jade, o ni ko si ohun to kan oun kan ọrọ Adeọṣun o, Buhari lo ranṣẹ pe oun o, ọtọ pata si ni ohun to pe oun fun. Iyẹn daa. Eyi naa lo si fa ibeere pe ṣe ọkunrin ojiṣẹ Ọlọrun yii ba Buhari sọ ootọ ọrọ. Eeyan ko ri oju rẹ nigba to jade lọdọ Buhari, boya o n rẹrin-in ni tabi o fa oju ro. Awọn Yoruba sọ pe bi ọmọ iya meji ba wọle lọ ti wọn sọrọ, ti wọn n jade bọ ti wọn n rẹrin-in kọlu ara wọn, irọ ni wọn lọọ pa funra wọn ninu ile. Lilọ ti Bakare lọ si ọdọ Buhari ṣe pataki, nitori Bakare yii lo fẹẹ ṣe igbakeji Buhari tẹlẹ nigba kan, ojiṣẹ Ọlọrun tun ni, bẹẹ lo jẹ ojulowo ọmọ Yoruba. Yatọ si eyi, Bakare wa ninu awọn ti Ọbasanjọ ba ṣe ipade ni bii ọsẹ meloo kan sẹyin lori bi wọn yoo ṣe le Buhari lọ. Pẹlu gbogbo eyi, o daju pe ọrọ yoo maa gbe Bakare ninu bi Buhari ti ṣe ranṣẹ si i pe oun fẹẹ ri i ni. Ki waa ni Bakare sọ fun Buhari o. Ṣe o ṣalaye pe Yoruba ati ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lodi si abule tabi ilu Fulani to fẹẹ da silẹ. Ṣe o jẹ ki Buhari mọ pe ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ni ko fẹ Fulani apaayan ni sakaani awọn. Ṣe Bakare jẹ ki Buhari mọ pe ara n ni awọn eeyan de gongo? Ṣe o jẹ ko mọ pe nnkan ko rọrun fẹni kan! Kin ni Tunde Bakare ba Buhari sọ o! Gbogbo ọmọ Naijiria lo n reti esi ayọ!

(48)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.