Ṣe nnkan mi-in wa ninu ọrọ yii ni

Spread the love

Wọn ni awọn aṣaaju APC ipinlẹ Ondo ko ti i yee ba ara wọn ja. Awọn baba isalẹ ẹgbẹ naa loriṣiiriṣii ti da si i, awọn majẹ-o-bajẹ ti wi tiwọn naa, Aṣiwaju Bọla Tinubu ati awọn agbaagba mi-in si ti gbe ẹronpileeni lọ sọhun-un, wọn ni ki wọn ma ja mọ, ki wọn jọ maa ṣe lo dara. Ṣugbọn ohun ti a n gbọ ni pe kinni naa ko ti i tan rara, koda, o tun fẹẹ maa le si i laarin wọn ni. Awọn ọlọgbọn ilu waa n beere lọwọ wọn pe, ṣe nnkan mi-in wa ninu ọrọ yii ni! Nigba ti ẹ ba ti ri awọn oloṣelu ti wọn n ja ajaku akata bayii laarin ara wọn, ki ẹ ti mọ pe ko si ohun to kan araalu ninu ija yii, wọn ko tori wọn ja rara, nitori ara wọn ni wọn ṣe kọju ija sira wọn. Bi ko ba jẹ nitori owo, yoo jẹ nitori ipo, nitori kaluku lo fẹẹ di gomina, eyi ti ko ṣe gomina fẹẹ di minisita tabi sẹnetọ, tabi ko jẹ olori awọn aṣofin. Bẹẹ awọn ipo yii naa, ẹni kan ni yoo di ipo kan mu, nibi ti bii ẹgbẹrun kan ba si ti n ja si awọn ipo yii, wọn yoo ja gbẹyin naa ni. Bẹẹ bo ba jẹ nitori awọn eeyan ilu ni, ọrọ naa ko ni i le, nitori bi ko bọ si ẹni kan lọwọ, bo ba ti le bọ si ẹgbẹ oṣelu wa lọwọ, gbogbo wa naa lo bọ si lọwọ yẹn. Ṣugbọn ko ri bẹẹ nilẹ yii, bi ko ba ti bọ si emi lọwọ, afi ki n maa ba ẹni to ba bọ si lọwọ ja, ka si da gbogbo ẹ ru, bi ẹgbẹ wa ba fẹẹ ja kulẹ ko ja kulẹ, bi iya si n jẹ araalu ko ṣe kinni kan. Ẹ jẹ yaa jawọ ninu ija yin, kẹ ẹ fi ti Ajimọbi ati awọn ara ipinlẹ Ọyọ ṣe arikọgbọn, bi bẹẹ kọ, ohun gbogbo yoo bọ sọnu mọ yin lọwọ, kaluku yoo si pada di alarinkiri. Ẹ jẹ yaa ronu yin wo.

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.