Ṣe ki i ṣe pe oku Abiọla lo n daamu Babangida bayii

Spread the love

Bi ẹni kan ba wa to yẹ ko maa gbadun aye ẹ bayii, Ọgagun Agba Ibrahim Babangida ni. Lara awọn ti wọn gbadun ninu iṣẹ ologun Naijiria, ti wọn si gbadun owo ijọba Naijiria, ọkan ni ọkunrin ti wọn n pe ni Maradona yii. Ṣugbọn Babangida ko gbadun, ọrọ meji to si sọ lọsẹ to kọja yii fi han pe ko gbadun aye rere rara. Akọkọ ni pe o ni oun ko le kọ iwe nipa ara oun, nitori ko sẹni ti yoo ka a, pe wọn ko ni i ka iwe oun nitori awọn ohun ti oun ti ṣe sẹyin. Ọrọ naa wuwo gan-an ni fun ẹni to ba mọ itumọ rẹ. Ko si ohun to maa n wu awọn olori orilẹ-ede aye gbogbo to ti ṣejọba ti wọn ti gbejọba silẹ ju ki wọn kọ itan ara wọn, ohun ti oju wọn ri, iriri wọn nigba ti wọn fi n ṣe olori ilu lọ. Ti Babangida tilẹ yatọ, nitori oun fẹran iwe ati imọ daadaa. Ṣugbọn oun lo sọ pe oun ko le kọ itan nipa ara oun tabi ijọba oun yii, to ni awọn ọmọ Naijiria koriira oun, wọn ko ni i ka iwe ti oun ba kọ. Lọna keji, Babangida ni awọn ọmọ Naijiria ki i gbe oriyin foun pe lati ọjọ ti Naijiria ti wa, oun loun ṣe eto idibo to dara julọ, eto idibo ti ko ni ojooro ati eru kankan ninu, eto idibo ti gbogbo aye ri, ti wọn si kede rẹ pe o dara julọ. Bi a ba wo ọrọ mejeeji yii, afaimọ ko ma jẹ Babangida ti n ṣe kantankantan, ko ma jẹ oku Abiọla ti n yọ si i. Abi bi ko ba jẹ bẹẹ, kin ni yoo fa iru ọrọ bẹẹ yẹn. Eto idibo to dara ju, eto idibo ti ko ni eru ati ojooro, ṣugbọn lẹyin ti o ṣeto idibo naa tan, o ko gbejọba silẹ fẹni to wọle. Ọrọ ọjọ naa ni Naijiria ko si ti i bọ ninu rẹ titi doni yii o. Wahala aye Abacha, ijangbọn awọn NADECO, biba eto ọrọ aje wa jẹ, ṣebi oun lo ba wa de ibi ti a wa yii, latari pe Babangida ṣeto idibo ko gbejọba fun Abiọla to wọle, wọn si fa ọrọ naa titi ti wọn fi pa ọkunrin oniṣowo naa sọgba ẹwọn. Eto idibo wo ni ko waa ni ojooro ninu o! Ṣe ti June 12 yii naa ni! Ko si ọmọ Naijiria kan ti yoo ranti ohun to ṣẹlẹ nigba naa, ati bi Naijiria ti ri ko too di asiko naa, ti ko ni i maa gbe Babangida ṣepe: yoo ṣepe fun un, yoo tun ṣepe fawọn ọmọ rẹ. Ẹkọ lo yẹ ki eleyii jẹ fun awọn ti wọn n ṣejọba loni-in yii, ati awọn oloṣelu ti wọn ro pe gbogbo agbara aye ati ọrun lo wa lọwọ awọn. Igba kan ti wa nilẹ yii to jẹ pe bi Babangida yii ba ni ki wọn paayan, wọn yoo pa a ni, bo ba ni ki wọn si sọ eeyan di olowo, lẹsẹkẹsẹ ni wọn yoo sọ ọ di olowo, gbogbo agbara pata ni Ọlọrun gbe le e lọwọ. Ṣugbọn bawo lo ṣe lo o? Bo ṣe lo o naa lo pada di wahala si i lọrun yii, ti igbẹyin aye rẹ ko si ni isinmi ati ifọkanbalẹ to tẹ ẹ lọrun, iyẹn lo ṣe fẹ ka ba oun daro. Ko sẹni to jẹ ba a daro, nigba to jẹ ere iṣẹ ọwọ rẹ lo n jẹ. Oloṣelu to ba n ṣe laulau kiri loni-in, tirẹ yoo buru ju ti Babangida lọ, nitori Ọlọrun o bimọ o, ẹsan lọmọ Olodumare, ko si aṣegbe kan nibi kan!

(154)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.