Ṣe ka sọ pe Ọlọrun lo mu Dino Melaye bayii

Spread the love

Ohun ti oju ọkunrin aṣofin ti wọn n pe ni Dino Melaye ri lọsẹ to kọja yii, koda titi di asiko ti a n wi yii, bi eeyan ba jokoo to sọ pe pe Ọlọrun lo mu Dino, awọn ti wọn ba mọ iwa ati iṣesi ọmọkunrin oloṣelu naa yoo sọ pe ootọ ni. Akọkọ ni pe fun ẹni ti ko ba mọ, ọmọ Yoruba ni Dino, ọkan ninu awọn ọmọ Yoruba ni Kogi ni. Asiko ti wọn dibo ni Kogi, ti ẹgbẹ APC fa Audu kalẹ, ti wọn si wọle, ṣugbọn ti Audu ku lojiji, Dino lawọn Buhari lo lati ri i pe ipo gomina ko bọ si ọmọ Yoruba to yẹ ki ipo naa bọ si lọwọ. Faleke ni igbakeji Audu, oun lo si yẹ ko di gomina lẹyin ti ọga rẹ ti wọn jọ du ipo naa ti ku. Amọ lojiji lawọn eeyan yii dide, awọn ọmọlẹyin Buhari si gbe ogun kalẹ, nitori wọn ko fẹ ko jẹTinubu ni yoo fa ẹni ti yoo ṣejọba Kogi kalẹ, wọn si lọọ fa Yahaya Bello ti ko si ninu ẹgbẹ wọn wa, wọn ni oun ni yoo ṣe gomina. Wọn lo agbara adajọ, wọn lo tawọn ti wọn n ṣeto idibo INEC, wọn si lo agbara ijọba apapọ lati maa ko oriṣiiriṣii irọ jọ. Gbogbo bi wọn ti n rin kiri yii, Dino Melaye ni wọn fi ṣe aṣaaju ati aṣoju wọn. Nigbẹyin, wọn gbe ọpa aṣẹ fun Yahaya Bello, Dino si sọ lọjọ ti wọn n ṣebura fun gomina naa pe ẹni to ba n ba Yahaya ja, Ọlọrun Ọba lo n ba ja. Ṣugbọn loni-in, Yahya Bello lo wa nidii gbogbo aburu to n ba Dino, awọn Buhari si fọwọ si i fun un. Ọtọ ni wọn ni ọkunrin naa n ko awọn apaayan kiri, ti awọn ọlọpaa si n tori ẹ le e kiri, ootọ si ni Yahya sọ pe awọn ara Kogi ko fẹ Dino mọ, wọn fẹẹ pe e wale lati ile igbimọ aṣofin to wa. Lọrọ kan, laarin oṣu kan si meji sẹyin, ohun to ti ba Dino laburu kọja ohun to ti ba oloṣelu adugbo wọn kankan ri. Loootọ, wọn n fi iya jẹ ẹ ni, awọn to ti lo o nigba kan ri naa lo pada n fiya jẹ ẹ, ṣugbọn ṣe wọn jẹbi ẹ ni! Oloṣelu, tabi eeyan kan to ba ti n fi ara rẹ silẹ fun awọn onibajẹ lo, onibajẹ loun naa, awọn ti wọn si lo o lati ba teeyan kan jẹ ni yoo pada ba toun naa jẹ, ohun to n ṣẹlẹ sọkunrin naa niyẹn. Ọlọrun yoo ko Dino yọ, amọ bo ba ti ja ajabọ ninu eyi, koun naa ma ṣe bẹẹ mọ o!

(180)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.