Ṣe ka sọ pe Ọlọrun lo mu baba ni

Spread the love

Ki ọrọ adajọ agba too ṣẹlẹ lojiji, o fẹrẹ jẹ ni gbogbo ọsẹ to kọja yii, ariwo aarẹ ana, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ni gbogbo eeyan n pa kiri. Ọbasanjọ tun kọwe si Buhari ni, iwe naa ko si dẹrun, iwe kan to le koko ni. Ṣugbọn ohun pataki kan ti iwe naa mu dani ni pe ododo ọrọ lo wa nibẹ, awọn ohun to n lọ lo wa ninu ẹ daadaa. Ọbasanjọ sọrọ bii ẹni ti ọrọ n dun, o sọrọ bii ẹni to nifẹẹ orilẹ-ede yii loootọ. Ọrọ to sọ ko dun mọ ọpọ eeyan ninu ṣaa o, nibẹ ni wọn si ti bẹrẹ eebu gidi fun un. Awọn kan ni ole loun naa, awọn kan ni gbogbo iwa toun naa hu lo n ni ki Buhari ma hu yii, awọn kan si sọ pe ẹnu rẹ ko gba gbogbo ohun to n sọ si Buhari yẹn si i. Bi ọrọ aye ti ri niyẹn. Ọbasanjọ ti ṣe awọn aidaa kan naa ni tirẹ, paapaa awọn ohun to ṣe fun wa nilẹ Yoruba nibi, to fihan pe oun fẹran Naijiria, koda, oun fẹran awọn mi-in ju iran Yoruba tirẹ lọ. Lara aṣiṣe ti oun naa yoo maa ronu rẹ bayii ni pe bo ba jẹ oun mọ ni, bo ba jẹ oun mọ ni, oun naa iba tọju Yoruba ju bi oun ti ṣe yii lọ. Ṣebi oun naa ti ri i pe ni Naijiria, kaluku lo n tọju adugbo rẹ, to n fi eeyan rẹ ṣaaju nibi ohun gbogbo. Jonathan ti ṣe tirẹ titi, awọn eeyan rẹ lo duro lẹyin rẹ lẹyin ti Ọbasanjọ ti ran an lọwọ lati wọle tan, awọn eeyan rẹ yii si ri i pe wọn le oun Ọbasanjọ jinna si i. Nitori ẹ lo ṣe ba Jonathan ja, to si fi gbogbo ara duro sẹyin Buhari ti iyẹn naa fi wọle, igba ti oun naa tun wọle tan nkọ, funra rẹ ati awọn eeyan rẹ tun ri i pe awọn le Ọbasanjọ jinna sile ijọba. Amọ kinni kan ni Jonathan ati Buhari yii ṣe ti wọn fi jọ ara wọn, iyẹn ni pe awọn eeyan wọn ni wọn n ko sibi iṣẹ, wọn si ṣeto awọn nnkan meremere fun adugbo wọn ju awọn ẹya to ku lọ. Ọbasanjọ ṣejọba tirẹ, o pa Yoruba ti, nitori o loun fẹran Naijiria ju ẹya oun lọ. Gbogbo eeyan lo n pariwo nigba naa pe ẹya ẹni lakọọkọ, nitori ẹya ẹni la kọkọ mọ, baba ẹni la kọkọ mọ ka too mọ ilu, ẹya ẹni la kọkọ mọ ka too mọ Naijiria lodidi. Amọ Ọbasanjọ ki i fẹẹ gbọ bẹẹ, yoo ni Naijiria lakọọkọ ni. Ni bayii, awọn araata to fi gbogbo aye fẹran, to n ran lọwọ, awọn naa ni wọn sọ ọ di ẹni-aiijiiri bayii, wọn ko fẹẹ ri i ni sakaani wọn, ko si fi bẹẹ naa niyi laarin awọn Yoruba, nitori oun naa mọ pe oun ko ṣe daadaa kankan si sakaani wọn ni gbogbo igba ti oun ni anfaani lati wa nile ijọba. Nitori bẹẹ, bi Ọbasanjọ ba sọrọ bayii bi awọn eeyan ba n bu u, oun naa yoo ṣe suuru ni, ohun to jẹ lo yo o. Tabi keeyan kuku sọ pe Ọlọrun lo moun naa. Ṣugbọn a ko gbọdọ tori iyẹn gbagbe awọn ọrọ gidi to ba sọ o, awọn ọrọ to ba jẹ pataki, afi ka ṣe amulo rẹ. Eyi to sọ nipa Buhari yii ko to ohun tawọn eeyan yoo tori rẹ maa ki ipọri rẹ fun un si, nitori ododo lo sọ. Ẹyin naa tẹ ẹ fẹran Buhari, ẹ kilọ fun un, nitori nigbẹyin, gbogbo ohun ti Ọbasanjọ n sọ yii ni yoo ṣẹ o, oju awọn araalu yoo si ja a, nitori iya to ba ti idi rẹ yọ, awọn araalu ni yoo fara ko o. Ki Ọlọrun ma jẹ ka jiya o.

 

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.