Ṣe ibo lawọn APC di yii ṣaa

Spread the love

Ọsẹ to kọja, lọjọ Satide yii, lo yẹ ki awọn ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP dibo abẹle wọn, awọn mejeeji si ṣe bẹẹ loootọ. Awọn APC gbarajọ si ilu Abuja, nibi ti wọn ti ṣe eto naa, ti ko si la ariwo kankan dani rara. Ko si ija, ko si ita, koda, ko si eebu rara. Ohun to si ṣẹlẹ naa ni pe loootọ ni wọn ni awọn fẹẹ dibo lati yan ẹni ti yoo du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ awọn lọdun 2019 ni, ṣugbọn apejọpọ naa ko jọ ti ẹni to waa dibo rara, nitori gbogbo wọn ti pinnu lọkan wọn pe ko sẹni ti yoo ba Buhari du ipo naa, ko si sẹni ti yoo tako o. Nidii eyi, ko sẹni to gba fọọmu olowo-nla ti wọn gbe kalẹ. Abi ta ni yoo fi miliọnu to le logoji ra fọọmu nitori ibo aarẹ, ti wọn yoo waa ja a kulẹ lojiji. Awọn eeyan ko tilẹ ni i dibo fun un, wọn o ni i sun mọ ọn paapaa, wọn yoo ni nitori to koju Buhari. Bẹẹ, ki i ṣe pe iwa ti Buhari n hu naa lo tẹ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ ati awọn aṣaaju ẹgbẹ naa lọrun, ibẹrubojo, ati ki ounjẹ ma bọ lẹnu kaluku ni wọn tori ẹ sa lọ, ki i ṣe pe wọn fẹran Buhari to bẹẹ naa ni. Bẹẹ ijọba dẹmokiresi ki i dara bi ko ba si alatako, iru ijọba bẹẹ, bii ijọba ologun ni, nitori ẹni ti wọn ba dibo fun bẹẹ, ohun to ba wu u ni yoo maa ṣe. Awọn APC ko ara wọn jọ bayii, wọn ni miliọnu mẹrinla lawọn, gbogbo awọn lawọn si dibo fun Buhari pe oun lawọn fẹ ko waa du ipo aarẹ lẹẹkeji, ko sẹni kan to le tako o ninu awọn, nitori ko sẹni to le ṣejọba ko da bii rẹ. Dajudaju, ẹtan ati irọ nla leleyii, bẹẹ ni ko ran ijọba dẹmokiresi lọwọ, o n ba a jẹ si i ni. Ijọba ti yoo ba ṣe anfaani gidi fun araalu, dandan ni ko ni alatako, alatako ti awọn to ṣeto dẹmokiresi si fi sinu rẹ, ki i ṣe ọta ẹni to n ṣejọba, ẹni ti yoo maa tako awọn eto to ba ṣe ko le ṣe daadaa ju bẹẹ lọ, tabi ko le tun awọn ohun to ba bajẹ ṣe ni. Bi ijọba ba ṣe oju ọna, alatako le ni ko daa, tabi pe ọna kan ṣoṣo lo ṣe ninu mẹwaa, ọjọ wo lo fẹẹ ṣe eyi to ku. Iyẹn ki i ṣe eebu, ki ijọba le tun sare bẹrẹ si i ṣe awọn ọna to ku ti wọn ko ti i ṣe ni. Ṣugbọn iru awọn ijọba APC ti ko fẹ alatako yii, ti ko sẹni to le duro niwaju aarẹ sọrọ, ti ko sẹni to le sọ pe ohun to ṣe ko dara ko le ṣe omi-in si i, afaimọ kijọba ọhun ma dijọba ṣọja. Ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, ẹni ti yoo tun ilẹ yii ṣe ni ki Ọlọrun gbe fun wa, bi APC ba si ti tun ile ara wọn ṣe, ko ni i sewu kankan fun wọn ni 2019.

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.