Ṣe gomina ni PDP fa kalẹ yii ṣa

Spread the love

Nibi ti aṣiṣe awa eeyan ti n bẹrẹ ree. Nibi ti wahala wa ti n ye ẹyin ree ti a ki i fura. Iṣoro wa fun adiyẹ lati ye ẹyin dudu, gẹgẹ bi iṣoro ṣe wa fun agbado ti a gbin lati hu tomaati jade. Irẹjẹ ko si ninu fọto, bi eeyan ba ṣe jokoo naa ni yoo ba ara rẹ bi fọto to ya ba jade. Bi ẹgbẹ PDP ba fẹran ara Ọṣun, yoo ṣoro ki wọn too sọ pe Ademọla Adeleke lawọn yoo gbe le awọn eeyan ipinlẹ naa lori. Bi ẹgbẹ PDP ba si kuna ibo naa lọjọ iwaju, tabi ti wọn ba wọle ti adajọ ba ni ki wọn gbejọba fawọn ti wọn ko wọle, iyẹn ko ni i jẹ pe APC tabi awọn oloṣelu mi-in lo n ṣe ẹgbẹ yii, awọn funra wọn ni wọn fi ọwọ ara wọn ṣe ara wọn. Nigba ti eeyan ba wo ori ẹrọ ayelujara, to ba ri Ademọla Adeleke nibi to ti n sọrọ, to n ṣalaye bi Dangote ṣe n pe oun ni Demoo, to ni oun n gbe owo bọ ni Ọṣun, to n sọ bi Ọtẹdọla ti n pe oun, to n pariwo pe oun ti de towotowo, oun ko de ti Naira ti Naira o, oun de ti dọla ti dọla ni, tọhun yoo mọ pe ko si nnkan kan lori ọkunrin yii ti yoo fi ṣe gomina odidi ipinlẹ bii ti Ọṣun. Nigba ti gomina ba n sọrọ bi ọkunrin yii ti sọrọ yii, ohun ti awọn oloyinbo n pe ni ẹmuti (empty) niyẹn, korofo lasan. Bi ẹnikẹni ba jokoo sibi kan to ba n sọ fun awọn PDP yii pe ọrọ sabukeeti ti ọkunrin yii ko ni yii, bi yoo ti lọ niyẹn, wọn n tan ara wọn jẹ ma ni, ọrọ naa yoo ru jade bo ba ya. Nidakeji, bi ọkunrin yii ba tilẹ wọle loootọ, to di gomina, pẹlu awọn ọrọ ti o n ti ẹnu rẹ jade yii, idagbasoke wo ni yoo mu ba ipinlẹ Ọṣun. Ki i ṣe ọrọ ija la n sọ yii o, eeyan mọ-ọn jo, o fẹran ijo, iyẹn kọ ni ko ma ni laakaye tabi ko ma paasi idanwo, iyẹn ko si ni ko ma ni nnkan kan ninu ori. Amọ bi eeyan ko ba ni kinni kan ni agbari, ko ni in naa niyẹn o, ko si sohun ti ẹnikẹni le ṣe si i. Ademọla Adeleke daa nijo jijo, o si daa bi ọrọ ba di ti faaji, ṣugbọn bo ba jẹ iṣẹ gomina lawọn PDP n pe ọkunrin yii si, wọn ko fẹran awọn ara Ọṣun, wọn ko si ka wọn si nnkan kan. Bi wọn yoo ṣe waa ṣe e ti ọkunrin naa yoo wọle yoo laju yin lasiko yii o.

 

 

(63)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.