Ṣe ẹ ti gbọ nipa awada tuntun to wa nigboro bayii!

Spread the love

Apara tawọn eeyan n fi ara wọn da bayii nigboro ni: “Ti ṣọọbu ẹ pa!” Awada tuntun ni, ibi ti wọn si ti ri i yoo ya awọn ti ko ba ti i mọ tẹlẹ lẹnu. Nibi ijiroro ti awọn ti wọn fẹẹ du ipo igbakeji aarẹ ilẹ yii ninu ibo ọdun to n bọ ṣe lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii. Yẹmi Ọṣinbajo to fẹẹ ṣegbakeji fun Buhari ati Peter Obi to fẹẹ ṣegbakeji fun Atiku ni wọn jọ pade ara wọn. Nigba naa ni ọrọ da lori bi eto ọrọ-aje ṣe bajẹ nitori awọn eto ti ijọba Naijiria n ṣe bayii lori ọrọ-aje wa. Ọṣinbajo ni ko si ohun ti awọn n ṣe ju pe awọn ole n waa jale, wọn n ji owo ati awọn ọja to wa ni ṣọọbu, awọn si ti ṣọọbu awọn pa, awọn jokoo sita, awọn mu ada dani, ẹnikẹni ti awọn ba si ri to n bọ, awọn ti ṣetan lati ṣa a pa. Iyẹn lo ṣe jẹ eto ti awọn n ṣe bayii pẹlu ọrọ-aje, “Ti ṣọọbu ẹ pa!” lorukọ ẹ. Ṣugbọn Obi da a lohun pe iwa omugọ ni ki oniṣọọbu kan tori ole to n ji owo ni ṣọọbu ẹ ko ti ṣọọbu naa pa, ebi ni yoo pa oniṣọọbu naa ku. O ni ohun to yẹ ki ẹni to ni ṣọọbu ṣe ni lati wa awọn ohun eelo igbalode ti wọn fi n mu ole to ba fẹẹ ji nnkan ninu ṣọọbu, awọn ẹrọ to jẹ bo ba ti fẹẹ mu kinni naa jade, yoo maa pariwo lapo ẹ ni, ko gbe kamẹra ti yoo ya aworan awọn ẹni to ba n wọle ati awọn ẹni to n jade sori oke nibẹ ko maa ya kaluku, ko si maa fidio wọn. Ko ṣeto awọn sikiọriti olootọ to le mu ole, ki wọn wa lẹnu ọna lati maa wo awọn to ba wọle ati awọn to ba jade.  Bi oniṣọọbu ba tori pe ole n ja to ti ṣọọbu ẹ pa, kin ni yoo maa jẹ. Ohun ti Obi sọ niyẹn, ọrọ ti Ọṣinbajo naa si sọ niyẹn. Ṣugbọn ni tododo, to ba jẹ eto “Ti ṣọọbu ẹ pa!” yii lawọn Buhari n lo lati ṣejọba wọn, ti wọn tori ole ti wọn ti ṣọọbu, ti wọn ko wo ti iya ti yoo jẹ awọn ọmọ wọn ati eeyan to ku, nitori wọn n ri owo ọfẹ ati awọn nnkan ọfẹ jẹ, eleyii ko ni i ṣe araalu ni anfaani kankan o. Aye awọn ọmọ Buhari la wa yii o, aye “Ti ṣọọbu ẹ pa!”

 

 

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.