Ṣe ẹ ri i, eeyan gbọdọ ni suuru laye yii o

Spread the love

Beeyan o ba ni suuru, to ba n fọrọ gbogbo binu, tabi to ba n wo iwa ti awọn eeyan n hu soun, tọhun yoo ṣe ara rẹ leṣe o. Abi nigba teeyan ba gbe hapatẹnṣan, ti wọn ba ni ẹjẹ ẹ n ru, ṣe ki i ṣe pe o ti fa ijangbọn si ara ẹ lọrun niyi. Ohun tawọn ọrẹ mi kan maa n sọ niyẹn, wọn aa ni Iya Biọla ki i ronu. Mo si maa n sọ fun wọn pe n o nironu ti mo n ro loootọ, nigba ti n ko ṣe aburu sẹni kan. Bi eeyan si ṣaburu si mi, emi o ki i ba wọn ja, n oo yaa yẹra fonitọhun ni. Bi mo ba ti yẹra fun un, mo mọ pe ko le ri mi ṣe nibi mọ, kaluku yoo wa laaye ara ẹ ni.

Ẹ ti gbagbe ọrẹ mi kan bayii nigba kan, nigba ti ko tiẹ ti i daa fun mi to bayii, ti mo gba sile nigba ti ọkọ ẹ ku, ti mo n bọ ọ, oun ati awọn ọmọ ẹ, ti mo tun n ko wọn lọ sileewe, to si jẹ niṣe lo gbẹyin mi to n lọọ ba Alaaji sun, boya Alaaji lo si n ba a sun ni, wọn ṣa n ba ara wọn sun ni otẹẹli kan ni Bọlade, ti wọn fi waa sọ fun mi ti mo lọọ ka wọn mọbẹ, ko sigba ti mo ronu ọrọ naa ti ki i dun mi pe mo lọ si otẹẹli lọọ fajangbọn. Nigba ti a kere niyẹn, iru iyẹn ko le ṣẹlẹ si mi mọ, bo wu ọrẹ mi kan ko waa gbe Alaaji, nigba to ba lo o tan, yoo da a pada fun mi. Iyẹn da mi loju.

Ṣugbọn mo jinna si obinrin yẹn o. O bẹ mi, mo si gbọ. Igba kan tiẹ wa to ni oun fẹẹ yawo kan lọwọ mi, mo ni n ko lowo ti n oo ya a, nigba ti mo si ri i pe owo ti o n wa yii agbara mi gbe e, mo fun un ni. Lo ba bẹrẹ si i paara ọdọ mi nitori ẹ, o fẹ ka tun maa ṣe ọrẹ wa, ṣugbọn mo yẹra fun un. Bi Ọlọrun ba ti fọta temi han mi, ko le ri mi pa mọ, nitori n oo yẹra fun un. Emi o mọ araa fi pamọ, ẹni ti mo ba n ba ṣe, gbogbo inu mi ni n oo ṣi silẹ fun un, amọ bo ba ti da mi lẹẹkan, kaluku yoo maa ba tirẹ lọ ni. N ko jẹ faaye ẹẹkeji silẹ, ko ma di pe yoo ri mi mu. Ọlọrun ma jẹ kaye mu wa.

Ohun ti mo ri ti ya mi lẹnu ju. O ya mi lẹnu, ṣugbọn n ko jẹ ko dun mi o. Ọrẹ wa kan lo n ṣode. N o tiẹ le pe e lọrẹẹ mi, ọkan ninu awọn aburo adugbo ni fun mi. Ọja la jọ wa, o si jẹ ọmọ daadaa si mi. Ko sibi to ti ri mi to jẹ ko ni i duro ki mi, yoo si fi orunkun ẹ mejeeji kunlẹ ni. Ọsẹ to lọ lọhun-un lo waa ba mi. Kin ni mo tiẹ n wi, o di ọsẹ kẹta bayii. O ṣaa waa ba mi lo ni oun ti ṣẹ mi. Lo ba kunlẹ, lo ni oun o ni i dide afi ti mo ba dariji oun. Nigba to si jẹ ọmọ daadaa ni, niṣe lemi naa n bẹ ẹ pe ko dide, mo ni gbogbo ohun yoowu to ba ṣe, mo ti yaafi ẹ.

Nigba naa ni inu ẹ too dun, o ni ọkan oun balẹ bayii, oun le sọ ẹṣẹ ti oun ṣẹ mi. Ni mo ba ni ki lo de, o lọmọ oun obinrin fẹẹ lọkọ ni, iyẹn ni Satide to kọja yii, o ni emi loun si fẹ ki n waa ṣe iya foun lọjọ naa. Mo ni, “Haa, ewo waa ni ẹṣẹ ninu iyẹn o.” O ni oun mọ bi ọwọ mi ṣe maa n di to ni, pe o yẹ ki oun ti waa sọ fun mi o kere, tan oṣu meji. Mo ni, “Ko ṣe nnkan kan, ṣebi ẹyin naa lẹ ba mi ṣe temi naa.” Ootọ si ni, ko si ibi ti ki i ba mi lọ bo ṣe wa yẹn, oun ni mo ni o fẹẹ fọ Iya Walia leti nigba ta a lọọ ṣe oku iya wa agba l’Abẹokuta nijọsi, tiyẹn n ṣe garagara nitori ọmọ onimọto kan to n yan lale nigba yẹn.

Ko sibi ti mo n lọ ti ko ni i tẹle mi, bẹẹ ni yoo si nawo ti yoo nara nibẹ. Ni mo ba ni mo ti gbọ, mo ti gba. O ni oun mu aṣọ, oun si fẹ ko jẹ emi ati oun nikan la maa wọ aṣọ naa, pe ọtọ ni eyi ti oun tun mu fun awọn ọrẹ oun ti awọn maa fi jo, ṣugbọn eyi ti oun fẹẹ fi sin ọmọ fọkọ yii, emi ati oun nikan loun fẹ ka jọ wọ ọ. Ni mo ba dupẹ lọwọ ẹ titi, mo ni Ọlọrun yoo pọn oun naa le. Mo ni eelo lowo aṣọ, o ni rara, oun ko gba owo, ki n ṣaa wọ ọ foun ni, oun ti ra a. N lo ba fa lailọọnu yọ, lo gbe e jade. Ọran lo da si mi lọrun yẹn, ọran gidi. To ba jẹ o sọ iye owo aṣọ ni, ko ni i si wahala nibẹ.

Ko le si wahala nibẹ nitori iye owo aṣọ awa mejeeji ni mo maa fun un. Ṣugbọn nigba ti ko sọ ọ yii, to ni oun ra a fun mi ni, mo mọ pe owo ti n oo fun un yoo ju owo aṣọ lọ. Mo ti foju wo aṣọ naa nigba to gbe e silẹ, mo mọ pe aṣọ olowo nla ni, ko le din ni ogoji ẹgbẹrun bo ṣe wa yẹn, nigba to si jẹ ti awa meji lo ra, ọgọrin ẹgbẹrun niyẹn maa jẹ. Ọlọrun si ṣe e, owo kan wa lọwọ mi tawọn onirẹsi ko wa, ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un meji ni, beeli meji si ni. Ni mo ba fa ọkan yọ nibẹ, mo gbe e le e lọwọ, mo ni owo ipalẹmọ niyẹn, ko lọọ maa mura silẹ. O ṣe adura titi ẹnu ẹ fẹrẹ bo.

Bi mo ṣe wa yii, emi o ki i kọja aaye mi. Ibi ti eeyan ba si pe mi si naa ni n oo lọ, ohun ti eeyan ba si ni ki n ṣe nibẹ naa ni n oo ṣe. Nigba ti wọn n pe iya ọmọ, aaye ọlọla lo ka mi si, to ni emi ni iya ọmọ, aburo mi loun, emi ni mo fẹẹ fọmọ lọkọ. A si ṣe gbogbo ẹyẹ naa fun un, inu emi naa si dun nitori gbogbo awọn ti wọn wa nibẹ naa ni wọn n pe Iya Biọla naa lo to bẹẹ, ti wọn n beere lọwọ ẹ pe bawo lo ṣe ri mi wọ wa si ode bẹẹ. Nigba ti wọn tun n jo, mo tun nawo fun wọn, emi o si n pẹ lode, nigba ta a ti pari tiyawo lakọọkọ, mo mura lati maa lọ ni. N lo ba n sin mi lọ, oun atawọn ọrẹ ẹ.

Ẹ ẹ waa mọ ohun to ṣẹlẹ, aṣe gbogbo bi a ṣe n ṣe yẹn, aṣe iyawo mi wa lode yẹn. Anti Sikira. O kuku wa nibẹ. Emi o mọ ẹni to pe e o, n o si mọ ẹni to ba wa, boya awọn ẹbi ọkọ lo ba wa ni o, emi o mọ. Mo tiẹ ṣẹṣẹ ranti ni, awọn ẹbi ọkọ ni, nitori kọlọ ti awọn ẹbi ọkọ wọ ni aṣọ to wọ wa sibẹ. Aṣe gbogbo bi mo ṣe n ṣe yẹn lo n wo mi, inu mi si dun siyẹn nitori oun naa fi maa mọ pe ẹni ti oun n ba fa a ki i ṣe ẹgbẹ ẹ, emi jinna si i pupọ, Ọlọrun lo fi mi ṣe olori fun un, ko si si ohun to le ṣe siyẹn. Igba ti mo n lọ lo n gboju sa fun mi, emi o si tete ri i, afi lẹẹkan naa toju wa ṣe mẹrin.

Ọlọrun wa ko ku si lẹyin alabosi, ohun ti kaluku ṣe ni yoo gba. Bi oju wa ṣe ṣe mẹrin ni mo ti mọ lẹẹkan naa pe o n gboju sa fun mi tẹlẹ, ṣugbọn ko ribi to fẹẹ sa si mọ, lo ba sare dide. Mo waa ṣẹṣẹ wo ẹgbẹ ẹ, ni mo ba fi ri ohun to jẹ ko maa gboju sa fun mi. Lode nibẹ, oun ati Iya Tọmiwa ni wọn jọ wa nibẹ. Aṣọ kan naa ni wọn wọ, gele kan naa ni wọn we. Anti Sikira ati Iya Tọmiwa, iru ọrẹ wo ni wọn n ba ara wọn ṣe! Nigba wo ni wọn tiẹ dọrẹ! Ṣebi emi ni mo pe oun ati ọkọ ẹ wa sile wa, wọn ko mọra nibi kan tẹlẹ! Iya Tọmiwa ti dọrẹ Anti Sikira. Ẹ ẹ ri i pe aye yii le.

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.