Ṣe Buhari yii gan-an o daayan mọ mọ ni

Spread the love

Ọrọ aidaayan mọ, ati airanti nnkan, to wa n ba Aarẹ Muhammadu Buhari ja yii yẹ ki gbogbo awọn agbaagba ilẹ yii mura si i o. Ohun to yẹ ki awọn oloṣelu ti wọn fẹẹ ṣeto idibo ba ara wọn sọrọ le lori ni, ohun to si yẹ ki awọn olori ijọba ti wọn ti ṣejọba nilẹ yii tẹlẹ jokoo sọ ni. Ki lo n ṣe Buhari to maa n gbagbe nnkan. Bo ba jẹ ẹẹkan lo ṣe e ni, wọn yoo ni aṣiṣe ni, bo ba jẹ ẹẹmeji ni, wọn aa ni o kan waye bẹẹ ni, ṣugbọn kinni naa ti di aṣa ojoojumọ, o fẹrẹ jẹ ko si gbangba ode kan ti Buhari yoo lọ ti ko ni i ṣi nnkan ṣe. Bi wọn ba darukọ ẹni to fẹẹ du ipo kan fun un bayii, ọtọ ni orukọ ti yoo pe, bi wọn ba sọ fun un pe bẹẹ kọ ti wọn tun ni ko tun un pe, ọtọ tun ni ohun ti yoo tun pe jade. Ọrọ naa tilẹ de oju rẹ nigba ti oun funra rẹ ko mọ pe oun ni oun n dupo aarẹ, to tun lọọ gbe aṣia fẹlomi-in nibi kampeeni ti wọn ṣe ni Delta, to si darukọ pe Great Ogboru ni yoo du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ wọn. Gbogbo aye lo pariwo iyẹn, eyi ti yoo si tun ṣe lọsẹ to kọja yii ni Cross River, nibi to ti kampeeni, to gbe asia gomina fun Sẹnetọ Ndoma Egba, yatọ si Owan Enoh to fẹẹ dupo naa lorukọ APC, bo tilẹ jẹ pe Adams Oshiomhole ti ṣe kilọkilọ fun ẹni to fẹẹ du ipo gomina naa, Owan Enoh, pe ko ma jinna si aarẹ. Iyẹn wa lẹgbẹẹ ẹ bayii o, ṣugbọn nigba to gbe aṣia soke, Ndoma lo gbe e fun, iyẹn si kọ ni yoo du ipo gomina. Kinni naa le da bii ere loju awọn eeyan, tabi pe ko ṣe kinni kan, ko niidi, ko si wahala ninu ẹ, ọpọ awọn ti wọn n ṣeto oṣelu ilẹ wa mọ pe iru igbagbe to n ṣe aarẹ yii yoo di eto ijọba rẹ lọwọ. Ko si bo ṣe le ṣe e, nigba ti awọn ti wọn n ba a ṣiṣẹ ba ti mọ pe bayii lo ṣe maa n gbagbe nnkan, awọn ohun buruku ni wọn yoo maa ṣe lọwọ ara tiwọn, koda ki aarẹ ni ero daadaa lọkan, awọn eeyan naa ni yoo maa ba a jẹ. Ta lo tiẹ mọ boya ohun to n ṣẹlẹ ree ti nnkan fi ri bo ṣe ri yii, ti ariwo si fi wa niluu pe Buhari kọ lo n ṣejọba, awọn kan lo n ba a ṣe e. Ko si ohun to buru bi awọn olori ijọba atijọ ba pe aarẹ si kọrọ nibi awọn ipade ti wọn maa n ṣe, ki wọn si ba a jiroro lori ohun to n ṣe e yii, ki wọn mọ boya aisan ni tabi aṣiṣe, bo ba si jẹ aisan, ki wọn mọ bo ṣe le to. Bo ba ṣe orilẹ-ede ti a ti gbọ ara wa ye la wa ni, ko si ohun to buru ninu iyẹn, bẹẹ ni ki i ṣe ọrọ APC tabi PDP, ọrọ to kan gbogbo Naijiria ni. Ẹ jẹ ka mọ ohun to n ṣe Buhari gan-an, ko ma tun di pe a oo kabaamọ bo ba dọla. Aburu o ni i ṣe aarẹ wa, aburu o si ni i ṣe awa naa o. Ṣugbọn ka ṣe e bo ti yẹ ka ṣe e, ko le ri bo ṣe yẹ ko ri o.

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.