Ṣe asiko yii to yẹ ki wọn yọ Fayoṣe niyi

Spread the love

Bi ori eeyan ba fẹẹ buru, yoo ṣoro fun un lati mọ iwa i hu, bi eeyan ko ba si ti ni iwa oriire, ko si bi yoo ti ṣee ti yoo ṣoriire. O da bii awọn kan wa lẹyin ẹgbẹ PDP nilẹ Yoruba, asasi ati eedi awọn APC ti mu wọn. Ẹni ti awọn eeyan fẹẹ sun jẹ ni wọn, nitori gbogbo ilu lo gba pe ole ni wọn, ẹgbẹ akowojẹ, bi eeyan ba si ti ranti awọn bii Ọbanikoro ati Baba Bọde George ti wọn tẹwọn de lọjọsi ki ile-ẹjọ too da wọn lare, inu yoo maa biiyan si ẹgbẹ ọhun ni. Amọ lasiko ti awọn kan n ronu pe boya ni ayipada ko ti de ba wọn, boya ni iya to jẹ wọn ko ti kọ wọn lọgbọn, awọn funra wọn ko ti i mọ eyi ti wọn yoo ṣe, iwa ika inu wọn sira wọn ju tawọn alatako wọn lọ. Abi ki leeyan yoo sọ nipa eyi ti awọn alaṣẹ PDP ṣe yii, ti wọn yọ Fayoṣe nipo olori ẹgbẹ naa ni ilẹ Yoruba laarin iwọnba igba to fi wa nitimọle awọn EFCC, ti wọn si ti sare fi Abiọdun Olujimi si i. Lododo, ohun ti ofin ẹgbẹ wọn sọ ni pe ẹni to ba di ipo oṣelu to ga julọ mu ni adugbo kan ni yoo ṣe olori ẹgbẹ naa ni adugbo rẹ, ṣugbọn o ti ya ju, nigba ti ki i ṣe pe Fayoṣe n lọ sibi kan tabi pe Olujimi naa n sa lọ niluu, tabi pe wọn ti ṣetan ti wọn fẹẹ pa ẹgbẹ PDP run. Ṣebi ohun yoowu ti wọn ba fẹẹ ṣe, wọn yoo duro ki Fayoṣe jade, wọn yoo si pe e lati ran an leti iwe ofin ẹgbẹ, ṣebi oun naa kuku gba ipo naa lọwọ ẹnikan ni. Ṣugbọn eyi ti ko dara nibẹ ni pe ọkunrin naa wa nitimọle awọn EFCC, wọn n wọ ọ lọ sile-ẹjọ, wọn n ba a fa wahala nitori ẹgbẹ wọn, ko si too de ẹ ti ṣepade, ẹ ti fi ẹlomi-in ṣe olori ẹgbẹ. Ṣe iyẹn waa jẹ pe Ọlọrun lo mu un niyẹn. Bo ba tilẹ jẹ pe Ọlọrun naa lo mu un nitori iwa ole toun naa hu ati iwa ọdaran toun ati Ọbanikoro jọ n hu nidii owo kikojẹ, ṣe ẹnu PDP la oo ti gbọ ọ ni. Ṣebi ẹgbẹ naa jẹ ẹgbẹ awọn ole lawọn ọmọ ẹgbẹ ṣe n jale lọ, ki lo waa de ti ẹ o tun maa jin ara yin lẹsẹ. Eleyii ko daa, bo ba si jẹ Fayoṣe ti gbogbo ilu mọ ni, afaimọ ki ẹgbẹ PDP ma ti kan posi ara wọn funra wọn. Nitori nigba ti awọn ẹmi to n ba Fayoṣe sọrọ ba tun pe e ba sọrọ, afaimọ ki ẹfuufulẹlẹ ma fẹ ẹ gba inu ẹgbẹ oṣelu mi-in lọ.

(28)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.