Ṣe Ajimọbi o ti ko ba APC n’Ibadan bayii

Spread the love

Awọn ero ti wọn wa nibi ti ẹgbẹ PDP ti ṣe ipolongo wọn n’Ibadan lọsẹ to kọja le debii pe ko si ibi ti iroyin ipolongo naa ko de. Bawo ni PDP yoo ṣe ri ero rẹpẹtẹ bẹẹ nibi to jẹ APC ni gomina wọn. Ọrọ naa gba ero gidi fun awọn ti wọn ba fẹ rere fun ẹgbẹ APC. Bi eeyan ba si n gbọ awọn orin ọtẹ ati orin owe ti wọn n kọ nibi ipolongo naa, ati bi awọn eeyan ṣe n fo soke ti inu wọn n dun, tọhun yoo mọ pe kekere kọ ni o. Ogun abẹle to n lọ ninu ẹgbẹ ADC ti Baba Ladọja ko awọn ọmọ ẹyin rẹ lọ ko le jẹ ki eeyan ronu pe ẹgbẹ naa yoo ri nnkan kan mu. Ladọja lo ko wọn lọ si ADC, to fa Fẹmi Lanlẹhin kalẹ, lojiji lo si kọyin si Lanlẹhin, to si fibinu kuro ninu ADC lọ sinu ZLP, ẹgbẹ ti ẹni kan ko mọ ibi to ti ṣẹlẹ ru yọ. Iyẹn lo ṣe ṣoro lati ronu ẹgbẹ naa ninu ibo gomina to n bọ. A a kuku si gburoo Alao Akala ni tiẹ. Loootọ ni baba naa loun fẹẹ ṣe gomina, ṣugbọn alọ la ri ni, a o rabọ, ipolongo rẹ ko ti i gbera nilẹ, eeyan ko si mọ ibi ti yoo gba yọ tabi ọjọ ti yoo de rara. Nitori bẹẹ, aarin APC ati PDP ni ija naa yoo ti gbona julọ. Bo ba jẹ tẹlẹ ni, ko si eeyan ti yoo ka ọrọ PDP si rẹpẹtẹ, ṣugbọn ohun ti wọn ṣe lọsẹ to kọja yii ṣẹruba awọn ti wọn mọ nipa ẹ. Ero naa papọju. Orin ti wọn si n kọ fihan pe Ajimọbi to n ṣe gomina ni wọn n ba wi. “Ẹ ti gbagbe ibo ni, ẹ ti gbagbe ibo ni, nigba t’ẹ n wole wa, t’ẹ n wosọ wa, ẹ ti gbagbe ibo ni!” Ohun ti wọn n wi ni pe Ajimọbi ti gbagbe pe oun yoo tun waa du ipo kan nigba to n wo ile awọn eeyan to si n wo isọ wọn. Bilẹ ba bọ si titi tabi to wa loju ọgbara, ijọba le wo o, amọ ijọba bẹẹ yoo ṣe alaye pẹlu ọrọ daadaa, yoo si ran awọn eeyan lọwọ lati ri ibomi-in. Yatọ si eyi, ọpọ awọn nnkan mi-in ni Ajimọbi ṣe ti ko ba eto ijọba dẹmokiresi mu. Iwọsi to fi n lọ awọn eeyan, abuku to fi n kan wọn, ati ọrọ bii pe ko-siru-mi laye mọ to kun ẹnu rẹ, asiko ẹsan ree, bi ọkunrin gomina alasọtan naa ko si ṣe ni i ko ba APC nipinlẹ Ọyọ bayii dọwọ Ọlọrun.

 

 

(20)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.