Ṣade dero kootu, wọn ni gbọmọ-gbọmọ ni

Spread the love

Awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko ti wọ obinrin kan, Ṣade Odubayọ, ẹni ọgbọn ọdun, lọ si kootu majisreeti to wa ni Ebute-Mẹta, niluu Eko, wọn ni o gbiyanju lati ji ọmọ ọdun mẹrin kan gbe.

Odubayọ, ẹni ti wọn ko sọ pato ibi to n gbe, ni Inspẹkitọ Chinalu Uwadione fẹsun ijinigbe kan, eyi ti obinrin naa sọ pe oun ko jẹbi rẹ.

Agbefọba naa ṣalaye pe ni nnkan bii aago marun-un aabọ irọlẹ ọjọ kin-in-ni, oṣu yii, ni olujẹjọ huwa yii ni ojule kẹrin, Opopona Lower, ni Ikorodu. Ọmọkunrin naa ni wọn lo jẹ ti Deshino Awogundade. Agbefọba naa ṣalaye pe asiko ti Odubayọ n fọgbọn tan ọmọ naa jade ni agbala ile awọn obi rẹ ni wọn ri i, ẹsun naa lo si tako ofin to de iwa ọdaran ti ipinlẹ Eko, tọdun 2015.

Ninu idajọ rẹ, Adajọ A.O Adedayọ faaye beeli silẹ fun olujẹjọ naa pẹlu idaji miliọnu Naira, ati oniduuro meji niye kan naa. O ni awọn oniduuro yii gbọdọ san owo-ori ọdun mẹta, o kere ju, ki wọn si fi iwe-ẹri rẹ han akọwe kootu.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii, lo sun igbẹjọ naa si.

(25)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.